Jump to content

Ngozi Ezeonu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ngozi Ezeonu
Ngozi Ezeonu In "Family Secret", 2016
Ọjọ́ìbíNgozi Ikpelue
Ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù karùn-ún ọdún 1965
ìlú Owerri
Orílẹ̀-èdèỌmọ Nàìjíríà
Iléẹ̀kọ́ gígaNigerian Institute of Journalism
Iṣẹ́Òṣèrébìnrin

Ngozi Ezeonu tí orúkọ àbísọ rẹ̀ ń jẹ́ Ngozi Ikpelue ni wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù karùn-ún ọdún 1965 (May 23rd 1965) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò àti akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ òníròyìn tẹ́lẹ̀ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin ìlúmọ̀ọ́kà nípa ṣíṣe ẹ̀dá-ìtàn Ìyá nínú sinimá àgbéléwò lédè Gẹ̀ẹ́sì àti Ìgbò. [1][2][3] Lọ́dún 2012, ó kópa nínú sinimá àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Adesuwa, èyí ló mú un gba àmìn ẹ̀yẹ Akádẹ́mì nínú sinimá gẹ́gẹ́ bí òṣèrébìnrin tó dára jùlọ níbi ayẹyẹ igbàmìẹ̀ẹ ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ 8th Africa Movie Academy Awards.

Ìgbà èwe rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí ní Ngozi Ezeonu ní ìlú Owerri. Kí ó tó di gbajúmọ̀ òṣèré ìlúmọ̀ọ́kà, ó kàwé gbàwé ẹ̀rí nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ìròyìn ní Nigerian Institute of Journalism, ó sìn ṣiṣẹ́ ní Radio Lagos àti Eko FM.[4]

Aáyan rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré sinimá àgbéléwò[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bí kíkópa ẹ̀dá-ìtàn ìyá, ó ti kọ́kọ́ kópa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá-ìtàn ọlọ́mọgé ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà rẹ̀ ṣíṣe. Lọ́dún 1993, ni gbajúgbajà olùdarí sinimá-àgbéléwò nì, Zeb Ejiro fún ní ipa amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀dá-ìtàn, tí ó pè ní Nkechi nínú sinimá àgbéléwò kan lédè Ìgbò, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Nneka The Pretty Serpent. Lẹ́yìn èyí, ó kópa nínú sinimá àgbéléwò mìíràn tí wọ́n pe àkọ́lé rẹ̀ ní Glamour Girls lọ́dún 1994, ó kópa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá-ìtàn tí wọ́n pè ní .[5]

Àtòjọ díẹ̀ lára àwọn sinimá-àgbéléwò rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ngozi tí kópa nínú sinimá àgbéléwò tí ó ju àádọ́jọ lọ, lára wọn ni;

  • Glamour Girls
  • Shattered Mirror
  • The Pretty Serpent
  • Tears of a Prince
  • Cry of a Virgin
  • Abuja Top Ladies
  • Family Secret
  • The Confessor
  • The Kings and Gods
  • Zenith of Sacrifice
  • A Drop of Blood
  • Divided Kingdom
  • Diamond Kingdom
  • God of Justice

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]